Orin Dafidi 112:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ yin OLUWA!Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA,tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀.

2. Àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ yóo jẹ́ alágbára láyé,a óo sì bukun ìran ẹni tí ó dúró ṣinṣin.

3. Ọlá ati ọlà yóo wà ní ilé rẹ̀,Òdodo rẹ̀ wà títí lae.

Orin Dafidi 112