Orin Dafidi 107:27-30 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Wọ́n ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n káàkiri bí ọ̀mùtí,gbogbo ọgbọ́n sì parẹ́ mọ́ wọn ninu.

28. Nígbà náà ni wọ́n ké pe OLUWA ninu ìpọ́njú wọn,ó sì yọ wọ́n ninu ìṣẹ́ wọn.

29. Ó mú kí ìgbì dáwọ́ dúró,ó sì mú kí ríru omi òkun rọlẹ̀ wọ̀ọ̀.

30. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ nígbà tí ilẹ̀ rọ̀,ó sì mú kí wọ́n gúnlẹ̀ sí èbúté ìfẹ́ wọn.

Orin Dafidi 107