Nọmba 9:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní oṣù kinni, ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu aṣálẹ̀ Sinai pé,

2. “Kí àwọn ọmọ Israẹli máa ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá ní àkókò rẹ̀.

3. Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù yìí, láti àṣáálẹ́ ni àwọn ọmọ Israẹli yóo ti máa ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí òfin ati ìlànà rẹ̀.”

4. Mose bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n ṣe Àjọ̀dún ìrékọjá.

5. Wọn sì ṣe é ní àṣáálẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù kinni ní aṣálẹ̀ Sinai. Àwọn eniyan náà ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fun wọn.

Nọmba 9