69. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,
70. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.
71. Ahieseri ọmọ Amiṣadai, kó akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia.
72. Ní ọjọ́ kọkanla ni Pagieli ọmọ Okirani, olórí àwọn ẹ̀yà Aṣeri mú ọrẹ tirẹ̀ wá.
73. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ẹbọ ohun jíjẹ.