13. Ọrẹ ẹbọ rẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ.
14. Àwo kòtò tí wọ́n fi wúrà ṣe kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari;
15. akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;
16. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.
17. Ó kó àwọn nǹkan wọnyi kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia: akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n jẹ́ ọrẹ ẹbọ Naṣoni, ọmọ Aminadabu.
18. Ní ọjọ́ keji ni Netaneli ọmọ Suari olórí ẹ̀yà Isakari mú ọrẹ tirẹ̀ wá.
19. Ọrẹ ẹbọ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ jẹ́ aadọrin ṣekeli, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ;
20. ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari;
21. akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò kan, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;
22. òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.
23. Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Wọ́n jẹ́ ọrẹ Netaneli ọmọ Suari.
24. Ní ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olórí ẹ̀yà Sebuluni mú ọrẹ tirẹ̀ wá.
25. Ọrẹ tirẹ̀ ni: àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní Àgọ́ Àjọ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ.
26. Ṣíbí wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá tí ó sì kún fún turari.
27. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun.
28. Òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.
29. Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan wá fún ẹbọ alaafia. Èyí ni ọrẹ Eliabu ọmọ Heloni.
30. Ní ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olórí ẹ̀yà Reubẹni mú ọrẹ tirẹ̀ wá.