10. Olukuluku alufaa yóo kó ohun tí wọ́n bá mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀.”
11. OLUWA sọ fún Mose pé
12. kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí aya ẹnìkan bá ṣìṣe, tí ó hu ìwà àìtọ́ sí i;
13. tí ọkunrin mìíràn bá bá a lòpọ̀, ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ kò ká wọn mọ́; ṣugbọn tí ó di ẹni ìbàjẹ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹlẹ́rìí nítorí pé ẹnìkankan kò rí wọn;
14. tabi bí ẹnìkan bá ń jowú tí ó sì rò pé ọkunrin kan ń bá iyawo òun lòpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀,
15. kí olúwarẹ̀ mú iyawo rẹ̀ wá sọ́dọ̀ alufaa, kí ó sì mú ọrẹ rẹ̀ tíí ṣe ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun ọkà baali wá fún alufaa. Kò gbọdọ̀ da òróró sí orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ fi turari sinu rẹ̀, nítorí pé ẹbọ owú ni, tí a rú láti múni ranti àìdára tí eniyan ṣe.
16. “Alufaa yóo sì mú kí obinrin náà dúró níwájú pẹpẹ OLUWA,
17. yóo da omi mímọ́ sinu àwo kan, yóo bù lára erùpẹ̀ ilẹ̀ Àgọ́ Àjọ sinu omi náà.