Nọmba 5:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose pé,

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n lé gbogbo àwọn adẹ́tẹ̀ kúrò ní ibùdó wọn, gbogbo àwọn tí ó ni ọyún lára ati ẹnikẹ́ni tí ó di aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú.

3. Ẹ kó wọn sí ẹ̀yìn odi kí wọn má baà sọ ibùdó yín di aláìmọ́ nítorí pé mò ń gbé inú rẹ̀ pẹlu àwọn eniyan mi.”

4. Àwọn ọmọ Israẹli sì yọ wọ́n kúrò láàrin wọn gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.

5. OLUWA sọ fún Mose pé:

6. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé nígbà tí ẹnikẹ́ni, bá dẹ́ṣẹ̀, tí ó bá rú òfin Ọlọ́run, tí olúwarẹ̀ sì jẹ̀bi, kí báà ṣe ọkunrin tabi obinrin,

7. olúwarẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó san ìtanràn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún iye owó náà lé e fún ẹni tí ó ṣẹ̀.

Nọmba 5