Nọmba 4:29-36 BIBELI MIMỌ (BM)

29. OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka iye àwọn ọmọ Merari ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

30. Kí o ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

31. Àwọn ọmọ Merari ni yóo máa ru àwọn igi férémù Àgọ́, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

32. Àwọn òpó àyíká àgbàlá ati ìtẹ́lẹ̀ wọn, àwọn èèkàn àgọ́, okùn wọn, ati gbogbo ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Olukuluku yóo sì mọ ẹrù tirẹ̀.

33. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Merari ninu Àgọ́ Àjọ nìyí. Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.”

34. Mose, Aaroni ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli ka àwọn ọmọ Kohati ní ìdílé-ìdílé gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

35. Láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé ẹni aadọta ọdún, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

36. Iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹrinla ó dín aadọta (2,750).

Nọmba 4