Nọmba 4:26-30 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Aṣọ ìkélé ti àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, aṣọ ìkélé fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá, ati okùn wọn, ati gbogbo àwọn ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Àwọn ni wọn óo máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó bá jẹ mọ́ àwọn nǹkan wọnyi.

27. Kí Mose yan àwọn ọmọ Geriṣoni sí ìtọ́jú àwọn ẹrù, kí ó sì rí i pé wọ́n ṣe gbogbo ohun tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá pa láṣẹ fún wọn nípa iṣẹ́ wọn.

28. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Geriṣoni ninu Àgọ́ Àjọ nìyí, Itamari ọmọ Aaroni alufaa ni yóo jẹ́ alabojuto wọn.”

29. OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka iye àwọn ọmọ Merari ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

30. Kí o ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

Nọmba 4