13. Wọn óo kó eérú kúrò lórí pẹpẹ, wọn óo fi aṣọ elése àlùkò bò ó.
14. Wọn óo kó gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ sórí rẹ̀, àwọn àwo turari, àmúga tí a fi ń mú ẹran, ọkọ́ tí a fi ń kó eérú, àwo kòtò ati gbogbo ohun èlò tí ó jẹ mọ́ pẹpẹ náà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ bò wọ́n, wọn óo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.
15. Nígbà tí ó bá tó àkókò láti tẹ̀síwájú, àwọn ìdílé Kohati yóo wá láti kó àwọn ohun èlò ibi mímọ́ lẹ́yìn tí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá ti bò wọ́n tán. Wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan àwọn nǹkan mímọ́ náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóo kú.
16. “Eleasari ọmọ Aaroni Alufaa ni yóo ṣe ìtọ́jú òróró fìtílà, ati turari olóòórùn dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ati òróró ìyàsímímọ́, ati gbogbo Àgọ́ náà. Yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ ati àwọn ohun èlò ibẹ̀.”
17. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,
18. “Ẹ má jẹ́ kí ìdílé Kohati parun láàrin ẹ̀yà Lefi,
19. ohun tí ẹ óo ṣe sí wọn nìyí kí wọ́n má baà kú: nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ jùlọ, Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ yóo wọ inú ibi mímọ́ lọ, wọn yóo sì sọ ohun tí olukuluku wọn yóo ṣe fún wọn, ati ẹrù tí olukuluku wọn yóo gbé.
20. Àwọn ìdílé Kohati kò gbọdọ̀ wọ inú ibi mímọ́ láti yọjú wo àwọn ohun mímọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá yọjú wò wọ́n yóo kú.”
21. OLUWA sọ fún Mose pé,
22. “Ka iye àwọn ọmọ Geriṣoni ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn:
23. ka àwọn ọkunrin wọn láti ẹni ọgbọ̀n ọdún títí dé aadọta, àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.
24. Iṣẹ́ ìsìn ti àwọn ọmọ Geriṣoni nìyí:
25. Àwọn ni yóo máa ru àwọn aṣọ ìkélé tí a fi ṣe ibi mímọ́, ati Àgọ́ Àjọ pẹlu àwọn ìbòrí rẹ̀, ati awọ ewúrẹ́ tí ń dán tí wọn fi bò ó, ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
26. Aṣọ ìkélé ti àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, aṣọ ìkélé fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá, ati okùn wọn, ati gbogbo àwọn ohun tí wọn ń lò pẹlu wọn. Àwọn ni wọn óo máa ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó bá jẹ mọ́ àwọn nǹkan wọnyi.