1. Àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ati ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu, wá sọ́dọ̀ Mose ati àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli,
2. wọ́n ní, “OLUWA pàṣẹ fun yín pé kí ẹ fi gègé pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan Israẹli. Ó sì pàṣẹ fun yín pé kí ẹ fi ilẹ̀-ìní arakunrin wa Selofehadi fún àwọn ọmọbinrin rẹ̀.
3. Ṣugbọn bí wọ́n bá lọ́kọ lára ẹ̀yà Israẹli mìíràn, a ó gba ilẹ̀-ìní wọn kuro ninu ilẹ̀-ìní awọn baba wa, ilẹ̀-ìní wọn yóo jẹ́ ti ẹ̀yà àwọn ọkọ wọn, èyí yóo sì mú kí ilẹ̀ wa dínkù.