3. Àwọn ìlú náà yóo jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, wọn óo máa gbébẹ̀. Ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú náà ká yóo wà fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati mààlúù wọn.
4. Kí ilẹ̀ pápá tí yóo yí àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi ká jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ láti ibi odi ìlú wọn siwaju.
5. Lẹ́yìn odi ìlú kọ̀ọ̀kan, kí ẹ wọn ẹgbaa igbọnwọ ní ìhà kọ̀ọ̀kan ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìhà gúsù, ati ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati ìhà àríwá; kí ìlú wà ní ààrin. Ilẹ̀ tí ẹ wọ̀n yìí ni yóo jẹ́ ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn.
6. Ninu àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi, mẹfa ninu wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. Lẹ́yìn ìlú mẹfa yìí, ẹ óo tún fún wọn ní ìlú mejilelogoji pẹlu ilẹ̀ tí ó yí wọn ká.
7. Gbogbo ìlú tí ẹ óo fún wọn yóo jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu ilẹ̀ pápá tí ó yí wọn ká.