21. tabi tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lù ú pẹlu ibinu tí ẹni náà sì kú. Apànìyàn náà yóo jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, yóo sì kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Arakunrin ẹni tí ó pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i.
22. “Ṣugbọn bí ẹnìkan bá ṣèèṣì paniyan, tí kì í ṣe pẹlu ìríra, kì báà jẹ́ pé ó fi ohun ìjà gún un, tabi kí ó ṣèèṣì ju nǹkan lù ú,
23. tabi bí ẹnìkan bá ṣèèṣì sọ òkúta láì wo ibi tí ó sọ òkúta náà sí, tí òkúta náà sì pa eniyan tí kì í ṣe pé ó ti fẹ́ pa olúwarẹ̀ tẹ́lẹ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀,
24. kí ìjọ eniyan Israẹli ṣe ìdájọ́ láàrin ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan ati arakunrin ẹni tí wọ́n pa, tí ó fẹ́ gbẹ̀san, gẹ́gẹ́ bí ìlànà yìí.
25. Kí ìjọ eniyan gba ẹni tí ó paniyan náà lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí wọ́n mú un pada lọ sí ìlú ààbò rẹ̀. Níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí tí olórí alufaa tí a fi òróró yàn yóo fi kú.
26. Ṣugbọn bí apànìyàn náà bá rékọjá odi ìlú ààbò rẹ̀,
27. tí arakunrin ẹni tí ó pa bá rí i tí ó sì pa á, olùgbẹ̀san náà kì yóo ní ẹ̀bi;
28. nítorí pé apànìyàn náà gbọdọ̀ dúró ní ìlú ààbò rẹ̀ títí tí olórí alufaa yóo fi kú, lẹ́yìn náà, ó lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.
29. Èyí yóo jẹ́ ìlànà ati òfin fun yín láti ìrandíran yín níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
30. “Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, ẹlẹ́rìí meji gbọdọ̀ jẹ́rìí sí i pé nítòótọ́ ni olúwarẹ̀ paniyan. Ẹ̀rí eniyan kan kò tó fún ẹjọ́ apànìyàn.