Nọmba 35:14-21 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Mẹta ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani ati mẹta ní ilẹ̀ Kenaani.

15. Wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ sibẹ.

16. “Ṣugbọn bí ẹnìkan bá fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀ tí ẹni náà sì kú, apànìyàn ni ẹni tí ó fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa òun náà.

17. Bí ó bá sọ òkúta lu arakunrin rẹ̀ tí arakunrin náà sì kú, apànìyàn ni; pípa ni wọn yóo pa òun náà.

18. Tabi tí ó bá fi ohun ìjà olóró lu arakunrin rẹ̀ tí ẹni náà sì kú, apànìyàn ni, pípa ni wọn yóo pa òun náà.

19. Arakunrin ẹni tí a pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i.

20. “Bí ẹnìkan bá kórìíra arakunrin rẹ̀, tí ó sì fi ohun ìjà gún un, tabi tí ó ju nǹkan lù ú láti ibi tí ó sápamọ́ sí, tí ẹni náà bá kú,

21. tabi tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lù ú pẹlu ibinu tí ẹni náà sì kú. Apànìyàn náà yóo jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, yóo sì kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Arakunrin ẹni tí ó pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i.

Nọmba 35