Nọmba 34:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Mú olórí kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.”

19. Àwọn olórí náà nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Juda, a yan Kalebu ọmọ Jefune.

20. Láti inú ẹ̀yà Simeoni, a yan Ṣemueli ọmọ Amihudu.

21. Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, a yan Elidadi ọmọ Kisiloni.

22. Láti inú ẹ̀yà Dani, a yan Buki ọmọ Jogili.

23. Láti inú ẹ̀yà Manase, a yan Hanieli ọmọ Efodu.

24. Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, a yan Kemueli ọmọ Ṣifitani.

25. Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a yan Elisafani ọmọ Parinaki.

26. Láti inú ẹ̀yà Isakari, a yan Palitieli ọmọ Asani.

27. Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, a yan Ahihudu ọmọ Ṣelomi.

28. Láti inú ẹ̀yà Nafutali, a yan Pedaheli ọmọ Amihudu.

29. Àwọn ni OLUWA pàṣẹ fún láti pín ilẹ̀ ìní náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.

Nọmba 34