Nọmba 34:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA sọ fún Mose pé,

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fun yín, gbogbo ilẹ̀ náà ni yóo jẹ́ tiyín. Àwọn ààlà ilẹ̀ yín nìwọ̀nyí.’

3. Ilẹ̀ yín ní ìhà gúsù yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Sini lẹ́bàá ààlà Edomu. Ààlà yín ní ìhà gúsù yóo jẹ́ láti òpin Òkun-Iyọ̀ ní ìlà oòrùn.

4. Yóo sì yí láti ìhà gúsù lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Akirabimu, yóo sì la aṣálẹ̀ Sini kọjá lọ títí dé ìhà gúsù Kadeṣi Banea ati títí dé Hasari Adari ati títí dé Asimoni.

5. Yóo sì yí láti Asimoni lọ dé odò Ijipti, òkun ni yóo sì jẹ́ òpin rẹ̀.

Nọmba 34