37. Láti Kadeṣi wọ́n lọ sí Òkè Hori, lẹ́bàá ilẹ̀ Edomu.
38. Aaroni alufaa gun Òkè Hori lọ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un, níbẹ̀ ni ó sì kú sí ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un, ogoji ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ijipti.
39. Aaroni jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọfa (123) nígbà tí ó kú ní Òkè Hori.
40. Ọba ìlú Aradi, ní ilẹ̀ Kenaani, tí ń gbé Nẹgẹbu gbúròó pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀.
41. Wọ́n kúrò ní Òkè Hori wọn lọ sí Salimona.
42. Wọ́n kúrò ní Salimona wọ́n lọ sí Punoni.
43. Láti Punoni wọ́n lọ sí Obotu.