13. Wọ́n kúrò ní Dofika, wọ́n lọ pàgọ́ sí Aluṣi.
14. Wọ́n kúrò ní Aluṣi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Refidimu níbi tí wọn kò ti rí omi mu.
15. Wọ́n kúrò ní Refidimu lọ sí aṣálẹ̀ Sinai.
16. Láti aṣálẹ̀ Sinai wọ́n lọ sí Kiburotu Hataafa.
17. Láti Kiburotu Hataafa wọ́n lọ sí Haserotu.
18. Láti Haserotu wọ́n lọ sí Ritima.
19. Láti Ritima wọ́n lọ sí Rimoni Peresi.
20. Láti Rimoni Peresi wọ́n lọ sí Libina.
21. Láti Libina wọ́n lọ sí Risa.
22. Láti Risa wọ́n lọ sí Kehelata.
23. Láti Kehelata wọ́n lọ sí Òkè Ṣeferi.
24. Láti Òkè Ṣeferi wọ́n lọ sí Harada.
25. Láti Harada wọ́n lọ sí Makihelotu.
26. Láti Makihelotu wọ́n lọ sí Tahati.
27. Láti Tahati wọ́n lọ sí Tẹra.
28. Láti Tẹra wọ́n lọ sí Mitika.
29. Láti Mitika wọ́n lọ sí Haṣimona.
30. Láti Haṣimona wọ́n lọ sí Moserotu.
31. Láti Moserotu wọ́n lọ sí Bene Jaakani.