39. Gbogbo àwọn ọmọ Lefi lọkunrin, láti ọmọ oṣù kan sókè tí Mose kà ní ìdílé-ìdílé, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA jẹ́ ẹgbaa mọkanla (22,000).
40. OLUWA sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí lọkunrin láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti ọmọ oṣù kan sókè, kí o sì kọ orúkọ wọn sílẹ̀.
41. Gba àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò awọn àkọ́bí ní Israẹli, sì gba àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, dípò àwọn àkọ́bí ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni OLUWA.”
42. Mose bá ka gbogbo àwọn àkọ́bí ninu àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.
43. Gbogbo àkọ́bí ọkunrin, gẹ́gẹ́ bí orúkọ wọn, lati ọmọ oṣù kan lọ sókè ní iye wọn, lápapọ̀, wọn jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba ati mẹtalelaadọrin (22,273).
44. OLUWA sọ fún Mose pé,