23. Àwọn ọmọ Geriṣoni yóo pàgọ́ tiwọn sẹ́yìn Àgọ́ Àjọ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn.
24. Eliasafu ọmọ Laeli ni yóo jẹ́ olórí wọn.
25. Àwọn ni yóo máa ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́ ati Àgọ́ Àjọ, aṣọ ìbòrí rẹ̀, ati aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀;
26. aṣọ tí wọ́n ń ta sí àgbàlá, aṣọ tí wọ́n ń ta sí ẹnu ọ̀nà àbáwọ àgbàlá tí ó yí ibi mímọ́ ati pẹpẹ ká, ati okùn, ati gbogbo nǹkan tí wọ́n ń lò pẹlu rẹ̀.
27. Kohati ni baba ńlá àwọn ọmọ Amramu ati àwọn ọmọ Iṣari, àwọn ọmọ Heburoni ati àwọn ọmọ Usieli.
28. Gbogbo àwọn ọkunrin tí a kà ninu wọn láti ọmọ oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbaarin ó lé ẹgbẹta (8,600). Àwọn ni wọ́n ń ṣe ìtọ́jú ibi mímọ́.