25. pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
26. “Ní ọjọ́ karun-un, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹsan-an, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.
27. Ẹ óo máa rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni,
28. pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
29. “Ní ọjọ́ kẹfa, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù mẹjọ, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.
30. Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni;
31. pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
32. “Ní ọjọ́ keje, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meje, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.
33. Ẹ óo rú ẹbọ yìí pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti ọjọ́ kinni,
34. pẹlu òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi kún ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.
35. “Ní ọjọ́ kẹjọ ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì ní gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.
36. Ẹ máa fi akọ mààlúù kan ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLÚWA.