Ní ìrọ̀lẹ́, kí o fi ọ̀dọ́ aguntan keji rúbọ bíi ti ẹbọ ohun jíjẹ òwúrọ̀ pẹlu ẹbọ ohun mímu rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA.