Nọmba 28:20-25 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ẹbọ ohun jíjẹ tí ẹ óo rú pẹlu wọn ni ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá lọ́nà mẹta òṣùnwọ̀n efa fún akọ mààlúù kan, ati ìdámárùn-ún òṣùnwọ̀n efa fún àgbò kan,

21. ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa fún ọ̀dọ́ aguntan kọ̀ọ̀kan;

22. ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fun yín.

23. Ẹ óo máa rú àwọn ẹbọ wọnyi yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ojoojumọ.

24. Báyìí ni ẹ óo ṣe rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí OLUWA ní ojoojumọ fún ọjọ́ meje náà yàtọ̀ sí ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun mímu ojoojumọ.

25. Ní ọjọ́ keje ẹ óo máa ní àpèjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan.

Nọmba 28