“Jọ̀wọ́, gbà wá láàyè láti gba orí ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà wọ inú oko yín, tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi kànga yín. Ojú ọ̀nà ọba ni a óo máa rìn títí a óo fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”