17. Lẹ́yìn náà, Àgọ́ Ẹ̀rí yóo ṣí, pẹlu àgọ́ àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n ti pàgọ́ yí Àgọ́ náà ká, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa ṣí, olukuluku ní ipò rẹ̀, pẹlu àsíá ẹ̀yà rẹ̀.
18. Àsíá ibùdó ẹ̀yà Efuraimu yóo máa wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọrí; Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí wọn.
19. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).
20. Ẹ̀yà Manase ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli, ọmọ Pedasuri, ni yóo sì jẹ́ olórí wọn.
21. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaafa ó lé igba (32,200).
22. Ẹ̀yà Bẹnjamini ni yóo pàgọ́ tẹ̀lé ẹ̀yà Manase; Abidoni, ọmọ Gideoni ni yóo sì jẹ́ olórí wọn.
23. Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogun ó lé egbeje (35,400).
24. Àpapọ̀ gbogbo àgọ́ Efuraimu ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí jẹ́ ọ̀kẹ́ marun-un ó lé ẹgbaarin ati ọgọrun-un (108,100). Àwọn ni wọn yóo jẹ́ ìpín kẹta tí àwọn ọmọ Israẹli bá fẹ́ ṣí láti ibùdó kan sí òmíràn.