Nọmba 19:19-22 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Yóo sì bu omi náà wọ́n aláìmọ́ náà ní ọjọ́ kẹta ati ikeje. Ní ọjọ́ keje, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Aláìmọ́ náà yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀ ninu omi, yóo sì di mímọ́ ní ìrọ̀lẹ́.

20. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ tí kò sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́, yóo jẹ́ aláìmọ́ sibẹ nítorí pé a kò tíì da omi ìwẹ̀nùmọ́ sí i lára. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ ibi mímọ́ OLUWA di aláìmọ́. A óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn ọmọ Israẹli.

21. Ẹ gbọdọ̀ pa ìlànà yìí mọ́ láti ìrandíran. Ẹni tí ó bá wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà sí aláìmọ́ lára gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan omi náà yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

22. Ohunkohun tí aláìmọ́ bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fọwọ́ kan ohun tí aláìmọ́ náà bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”

Nọmba 19