4. Wọn óo máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ wọn ninu Àgọ́ Àjọ pẹlu rẹ. Ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi kò gbọdọ̀ bá ọ ṣiṣẹ́.
5. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ nìkan ni yóo máa ṣiṣẹ́ ninu ibi mímọ́ ati níbi pẹpẹ, kí ibinu mi má baà wá sórí àwọn ọmọ Israẹli mọ́.
6. Mo ti yan àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọ. Wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn fún OLUWA, wọn óo sì máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.
7. Ṣugbọn ìwọ pẹlu àwọn ọmọ rẹ nìkan ni alufaa ti yóo máa ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ ati níbi aṣọ ìbòjú. Èyí ni yóo jẹ́ iṣẹ́ yín nítorí ẹ̀bùn ni mo fi iṣẹ́ alufaa ṣe fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ yóo kú.”