1. OLUWA sọ fún Mose pé,
2. “Gba ọ̀pá mejila láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀pá kọ̀ọ̀kan láti ọwọ́ olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí o sì kọ orúkọ olukuluku sí ara ọ̀pá tirẹ̀.
3. Kọ orúkọ Aaroni sí ọ̀pá tí ó wà fún ẹ̀yà Lefi, nítorí pé ọ̀pá kan ni yóo wà fún olórí kọ̀ọ̀kan.
4. Kí o kó wọn sílẹ̀ níwájú Àpótí Ẹ̀rí ninu Àgọ́ Àjọ mi, níbi tí mo ti máa ń pàdé rẹ.
5. Ọ̀pá ẹni tí mo bá yàn yóo rúwé; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí ọ.”
6. Mose sọ èyí fún àwọn ọmọ Israẹli. Olórí àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan mú ọ̀pá wọn wá fún Mose, gbogbo rẹ̀ jẹ́ mejila, ọ̀pá Aaroni sì wà ninu wọn.