7. kí ẹ fi iná sinu wọn, kí ẹ sì gbé wọn lọ siwaju OLUWA. Ẹni tí OLUWA bá yàn ni yóo jẹ́ ẹni mímọ́; ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, ẹ̀yin ọmọ Lefi!”
8. Mose bá kọjú sí Kora, ó ní: “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọmọ Lefi!
9. Ṣé nǹkan kékeré ni, pé Ọlọrun Israẹli yà yín sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ OLUWA, ati fún ìjọ eniyan Israẹli?
10. OLUWA ti fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ Lefi yòókù ní anfaani yìí, ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń ṣe ojú kòkòrò sí iṣẹ́ alufaa.