42. Ẹ má lọ nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín.
43. Ẹ óo kú nígbà tí ẹ bá ń bá àwọn ará Amaleki ati Kenaani jagun. OLUWA kò ní wà pẹlu yín nítorí pé ẹ ti ṣe àìgbọràn sí i.”
44. Sibẹsibẹ àwọn eniyan náà lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Àpótí Majẹmu OLUWA tabi Mose kò kúrò ní ibùdó.
45. Àwọn ará Amaleki ati Kenaani tí ń gbé ibẹ̀ bá wọn jagun, wọ́n ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì lé wọn títí dé Horima.