Nọmba 13:20-23 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ẹ wò bóyá ilẹ̀ náà jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú, ẹ wò ó bóyá igi wà níbẹ̀ tabi kò sí. Ẹ múra gírí kí ẹ sì mú ninu èso ilẹ̀ náà bọ̀.” (Àkókò náà sì jẹ́ àkókò àkọ́so àjàrà.)

21. Àwọn eniyan náà lọ, wọ́n sì wo ilẹ̀ náà láti aṣálẹ̀ Sini títí dé Rehobu ati ni ẹ̀bá ibodè Hamati.

22. Wọ́n gba ìhà gúsù gòkè lọ sí Heburoni, níbi tí àwọn ẹ̀yà Ahimani, ati ti Ṣeṣai ati ti Talimai, àwọn òmìrán ọmọ Anaki ń gbé. (A ti tẹ Heburoni dó ní ọdún meje ṣáájú Soani ní ilẹ̀ Ijipti.)

23. Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Eṣikolu, wọn gé ṣiiri àjàrà kan tí ó ní èso. Ṣiiri àjàrà yìí tóbi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé àwọn meji ni wọ́n fi ọ̀pá gbé e. Wọ́n sì mú èso pomegiranate ati èso ọ̀pọ̀tọ́ wá pẹlu.

Nọmba 13