1. OLUWA sọ fún Mose pé,
2. “Rán amí lọ wo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó bá jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ni kí o rán.”
3. Mose bá rán àwọn ọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn lọ, láti aṣálẹ̀ Parani.
4. Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ó rán Ṣamua ọmọ Sakuri;
5. láti inú ẹ̀yà Simeoni, ó rán Ṣafati ọmọ Hori;
6. láti inú ẹ̀yà Juda, ó rán Kalebu, ọmọ Jefune;