1. OLUWA sọ fún Mose pé,
2. “Rán amí lọ wo ilẹ̀ Kenaani tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó bá jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ni kí o rán.”
3. Mose bá rán àwọn ọkunrin tí wọ́n jẹ́ olórí ninu ẹ̀yà wọn lọ, láti aṣálẹ̀ Parani.
4. Orúkọ wọn nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Reubẹni, ó rán Ṣamua ọmọ Sakuri;
5. láti inú ẹ̀yà Simeoni, ó rán Ṣafati ọmọ Hori;
6. láti inú ẹ̀yà Juda, ó rán Kalebu, ọmọ Jefune;
7. láti inú ẹ̀yà Isakari, ó rán Igali, ọmọ Josẹfu;
8. láti inú ẹ̀yà Efuraimu, ó rán Hoṣea ọmọ Nuni;
9. láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ó rán Paliti, ọmọ Rafu;
10. láti inú ẹ̀yà Sebuluni, ó rán Gadieli, ọmọ Sodi;
11. láti inú ẹ̀yà Josẹfu, tí í ṣe ẹ̀yà Manase, ó rán Gadi, ọmọ Susi;