51. OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.
52. Kí àwọn ọmọ Israẹli yòókù pa àgọ́ wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, olukuluku ní ibùdó rẹ̀, lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀.
53. Ṣugbọn àwọn ọmọ Lefi ni kí wọ́n pàgọ́ yí Àgọ́-Ẹ̀rí ká, kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ Lefi má baà súnmọ́ Àgọ́ náà, kí n má baà bínú sí àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ọmọ Lefi ni yóo máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.”
54. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.