46. jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ eniyan o le egbejidinlogun ó dín aadọta (603,550).
47. Ṣugbọn wọn kò ka àwọn ọmọ Lefi mọ́ wọn,
48. nítorí pé OLUWA ti sọ fún Mose pé,
49. kí ó má ka ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí ó bá ń kà wọ́n.
50. Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká.
51. OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.