20. Ninu ẹ̀yà Reubẹni, tíí ṣe àkọ́bí Israẹli, àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹni ogún ọdún sókè, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
21. jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500).
22. Ninu ẹ̀yà Simeoni, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
23. jẹ́ ẹgbaa mọkandinlọgbọn ó lé eedegbeje (59,300).
24. Ninu ẹ̀yà Gadi, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
25. jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé aadọta lé ní ẹgbẹjọ (45,650).
26. Ninu ẹ̀yà Juda, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
27. jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600).
28. Ninu ẹ̀yà Isakari, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
29. jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlọgbọn ó lé irinwo (54,400).
30. Ninu ẹ̀yà Sebuluni, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé
31. jẹ́ ẹgbaa mejidinlọgbọn ó lé egbeje (57,400).
32. Ninu ẹ̀yà Efuraimu àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé