36. Wò ó ẹrú ni wá lónìí lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa pé kí wọ́n máa gbádùn àwọn èso inú rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára ibẹ̀. Wò ó, a ti di ẹrú lórí ilẹ̀ náà.
37. Àwọn ọrọ̀ inú rẹ̀ sì di ti àwọn ọba tí wọn ń mú wa sìn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, wọ́n ń lo agbára lórí wa ati lórí àwọn mààlúù wa bí ó ṣe wù wọ́n, a sì wà ninu ìpọ́njú ńlá.”
38. Nítorí gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọnyi, a dá majẹmu, a sì kọ ọ́ sílẹ̀, àwọn ìjòyè wa, ati àwọn ọmọ Lefi ati àwọn alufaa fi ọwọ́ sí i, wọ́n sì fi èdìdì dì í.