27. Nítorí náà, o fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá sì jẹ wọ́n níyà, nígbà tí ìyà ń jẹ wọ́n, wọ́n ké pè ọ́, o sì gbọ́ igbe wọn lọ́run, gẹ́gẹ́ bí àánú rẹ ńlá, o gbé àwọn kan dìde bíi olùgbàlà láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
28. Ṣugbọn lẹ́yìn tí wọ́n ti ní ìsinmi tán, wọ́n tún ṣe nǹkan burúkú níwájú rẹ, o sì tún fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn. Sibẹsibẹ, nígbà tí wọ́n ronupiwada tí wọ́n sì gbadura sí ọ, o gbọ́ lọ́run, lọpọlọpọ ìgbà ni o sì gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ.
29. Ò sì máa kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n lè yipada sí òfin rẹ. Sibẹ wọn a máa hùwà ìgbéraga, wọn kìí sìí pa òfin rẹ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ wọn a máa ṣẹ̀ sí òfin rẹ, tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá pamọ́, ẹni náà yóo yè. Ṣugbọn wọn ń dágunlá, wọ́n ń ṣe orí kunkun, wọn kò sì gbọ́ràn.
30. Ọpọlọpọ ọdún ni o fi mú sùúrù pẹlu wọ́n, tí o sì ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ, láti ẹnu àwọn wolii rẹ, sibẹ wọn kò fetí sílẹ̀. Nítorí náà ni o ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ṣẹgun wọn.
31. Ṣugbọn nítorí àánú rẹ ńlá, o kò jẹ́ kí wọ́n parun patapata, bẹ́ẹ̀ ni o kò pa wọ́n tì, nítorí pé Ọlọrun olóore ọ̀fẹ́ ati aláàánú ni ọ́.
32. “Nítorí náà, nisinsinyii Ọlọrun wa, Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, Ọlọrun tí ó bani lẹ́rù, Ọlọrun tí máa ń mú ìlérí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣẹ, má fi ojú kékeré wo gbogbo ìnira tí ó dé bá wa yìí, ati èyí tí ó dé bá àwọn ọba wa, ati àwọn olórí wa, àwọn alufaa wa, ati àwọn wolii wa, àwọn baba wa, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ, láti ìgbà àwọn ọba Asiria títí di ìsinsìnyìí.
33. Sibẹ, o jàre gbogbo ohun tí ó dé bá wa yìí, nítorí pé o ṣe olóòótọ́ sí wa, àwa ni a hùwà burúkú sí ọ.