Nehemaya 7:16-26 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbẹta lé mejidinlọgbọn (628).

17. Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbaa ó lé ọọdunrun ati mejilelogun (2,322).

18. Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ọtalelẹgbẹta ati meje (667).

19. Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹtadinlaadọrin (2,067).

20. Àwọn ọmọ Adini jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín marun-un (655).

21. Àwọn ọmọ Ateri tí wọn ń jẹ́ Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un.

22. Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ ọọdunrun ó lé mejidinlọgbọn (328).

23. Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹrinlelogun (324).

24. Àwọn ọmọ Harifi jẹ́ aadọfa ó lé meji (112).

25. Àwọn ọmọ Gibeoni jẹ́ marundinlọgọrun-un.

26. Àwọn ará Bẹtilẹhẹmu ati Netofa jẹ́ ọgọsan-an ó lé mẹjọ (188).

Nehemaya 7