14. Mo dìde, mo wò yíká, mo bá sọ fún àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan yòókù pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. Ẹ ranti OLUWA tí ó tóbi tí ó sì bani lẹ́rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arakunrin yín, ati àwọn ọmọkunrin yín, àwọn ọmọbinrin yín, ati àwọn iyawo yín, ati àwọn ilé yín.”
15. Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa ti gbọ́ pé a ti mọ àṣírí ète wọn, ati pé Ọlọrun ti da ìmọ̀ wọn rú, gbogbo wa pada sí ibi odi náà, olukuluku sì ń ṣe iṣẹ́ tirẹ̀.
16. Láti ọjọ́ náà, ìdajì àwọn òṣìṣẹ́ mi ní ń bá iṣẹ́ odi mímọ lọ, ìdajì yòókù sì dira pẹlu ọ̀kọ̀, àṣíborí, ọrun ati aṣọ ogun. Àwọn ìjòyè sì wà lẹ́yìn gbogbo àwọn eniyan Juda,
17. tí ń mọ odi lọ́wọ́. Àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ń fi ọwọ́ kan ṣiṣẹ́, wọ́n sì mú ohun ìjà ní ọwọ́ keji.
18. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ náà fi idà kọ́ èjìká bí ó ṣe ń mọ odi lọ. Ẹni tí ó ń fọn fèrè sì wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ mi.