Nehemaya 2:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní oṣù Nisani, ní ogún ọdún tí Atasasesi ọba gorí oyè, mo gbé ọtí waini tí ó wà níwájú rẹ̀ fún un. N kò fajúro níwájú rẹ̀ rí.

2. Nítorí náà, ọba bi mí léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi fajúro? Ó dájú pé kò rẹ̀ ọ́. Ó níláti jẹ́ pé ọkàn rẹ bàjẹ́ ni.”

Nehemaya 2