19. Nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣú ní àwọn Ẹnubodè Jerusalẹmu kí ó tó di ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí wọ́n ti gbogbo ìlẹ̀kùn, ati pé wọn kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀ títí tí ọjọ́ ìsinmi yóo fi rékọjá. Mo yan díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ mi sí àwọn ẹnubodè náà, kí wọ́n má baà kó ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.
20. Gbogbo àwọn oníṣòwò ati àwọn tí wọn ń ta oríṣìíríṣìí nǹkan sùn sí ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu bíi ẹ̀ẹ̀kan tabi ẹẹmeji.
21. Ṣugbọn mo kìlọ̀ fún wọn, mo sì sọ fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ odi? Bí ẹ bá tún ṣe bẹ́ẹ̀ n óo jẹ yín níyà.” Láti ìgbà náà ni wọn kò wá ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.
22. Mo kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n wá láti ṣọ́ àwọn ẹnubodè, kí wọn lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.Ranti eléyìí fún rere mi, Ọlọrun mi, kí o sì dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀.