34. Juda, Bẹnjamini ati Ṣemaaya, ati Jeremaya.
35. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ alufaa tẹ̀lé wọn pẹlu fèrè.Àwọn nìwọ̀nyí: Sakaraya, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Matanaya, ọmọ Mikaaya, ọmọ Sakuri, ọmọ Asafu,
36. ati àwọn arakunrin rẹ̀ wọnyi: Ṣemaaya, Asareli ati Milalai, Gilalai, Maai ati Netaneli, Juda, ati Hanani, pẹlu àwọn ohun èlò orin Dafidi eniyan Ọlọ́run. Ẹsira, akọ̀wé, ni ó ṣáájú, àwọn eniyan sì tẹ̀lé e.