3. Nítorí náà, OLUWA yóo kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀ títí tí ẹni tí ń rọbí yóo fi bímọ; nígbà náà ni àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù yóo pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli.
4. Yóo dìde, yóo sì mójútó àwọn eniyan rẹ̀ pẹlu agbára OLUWA, àní, ninu ọláńlá orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Wọn óo máa gbé ní àìléwu, nítorí yóo di ẹni ńlá jákèjádò gbogbo ayé.
5. Alaafia yóo sì wà, òun gan-an yóo sì jẹ́ ẹni alaafia.Nígbà tí àwọn ará Asiria bá wá gbógun tì wá, tí wọ́n bá sì wọ inú ilẹ̀ wa, a óo rán àwọn olórí wa ati àwọn akikanju láàrin wa láti bá wọn jà.