19. Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, kì í ṣe ẹja ni ẹ óo máa pamọ́, eniyan ni ẹ óo máa fà wá.”
20. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
21. Bí ó ti kúrò níbẹ̀ tí ó lọ siwaju díẹ̀ sí i, ó rí àwọn arakunrin meji mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀. Wọ́n wà ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó bá pè wọ́n.
22. Lẹsẹkẹsẹ, wọ́n fi ọkọ̀ ati baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀lé e.
23. Jesu wá ń kiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo oríṣìíríṣìí àrùn sàn lára àwọn eniyan.
24. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Siria. Àwọn eniyan ń gbé gbogbo àwọn tí ó ní oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn tí ẹ̀mí Èṣù ń dà láàmú, ati àwọn tí wárápá mú ati àwọn arọ; ó sì ń wò wọ́n sàn.
25. Ọpọlọpọ eniyan ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili ati Ìlú Mẹ́wàá ati Jerusalẹmu ati Judia, ati láti òdìkejì Jọdani.