7. Ẹ̀yin alaiṣootọ! Òtítọ́ ni Aisaya ti sọtẹ́lẹ̀ nípa yín nígbà tí ó wí pé,
8. ‘Ọlọrun sọ pé:Ẹnu lásán ni àwọn eniyan wọnyi fi ń bọlá fún mi,ọkàn wọn jìnnà pupọ sí mi.
9. Asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí,ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni bí ẹni pé òfin Ọlọrun ni.’ ”
10. Ó wá pe àwọn eniyan jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́, kí ó sì ye yín.
11. Kì í ṣe ohun tí ó ń wọ ẹnu ẹni lọ ni ó ń sọni di aláìmọ́, bíkòṣe ohun tí ó ń jáde láti ẹnu wá ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.”
12. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ó bí wọn ninu?”
13. Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi tí ń bẹ lọ́run kò bá gbìn ni a óo hú dànù.
14. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tí ó ń fọ̀nà hanni ni wọ́n. Bí afọ́jú bá ń fọ̀nà han afọ́jú, àwọn mejeeji yóo jìn sinu kòtò.”