35. Ẹni rere a máa sọ ọ̀rọ̀ rere jáde láti inú ìṣúra rere; eniyan burúkú a sì máa sọ ọ̀rọ̀ burúkú jáde láti inú ìṣúra burúkú.
36. “Ṣugbọn mo sọ fun yín pé gbogbo ọ̀rọ̀ tí eniyan bá ń sọ láì ronú ni yóo dáhùn fún ní ọjọ́ ìdájọ́.
37. Nítorí nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo fi dá ọ láre; nípa ọ̀rọ̀ rẹ ni a óo sì fi dá ọ lẹ́bi.”
38. Ní àkókò náà ni àwọn kan ninu àwọn amòfin ati ninu àwọn Farisi bi í pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ rí àmì láti ọwọ́ rẹ.”
39. Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìran burúkú ati ìran oníbọkúbọ ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fi fún un àfi àmì Jona wolii.
40. Nítorí bí Jona ti wà ninu ẹja ńlá fún ọjọ́ mẹta tọ̀sán-tòru, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo wà ninu ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹta, tọ̀sán-tòru.
41. Àwọn ará Ninefe yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́, wọn yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nítorí iwaasu tí Jona wà fún wọn. Wò ó, ẹni tí ó ju Jona lọ ló wà níhìn-ín.
42. Ọbabinrin láti ilẹ̀ gúsù yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́ yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí ó wá láti ọ̀nà jíjìn láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni. Ẹ wò ó, ẹni tí ó ju Solomoni lọ ló wà níhìn-ín.
43. “Nígbà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ẹnìkan, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ilẹ̀ gbígbẹ láti sinmi. Ó ń wá ibi tí yóo fi ṣe ibùgbé, ṣugbọn kò rí.
44. Ó bá ni, ‘N óo tún pada sí ilé mi, níbi tí mo ti jáde kúrò.’ Nígbà tí ó débẹ̀, ó rí i pé ibẹ̀ ṣófo, ati pé a ti gbá a, a sì ti tọ́jú rẹ̀ dáradára.
45. Ó bá lọ, ó kó àwọn ẹ̀mí meje mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n bá wọlé, wọ́n ń gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìran burúkú yìí.”
46. Bí Jesu ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ ni ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ bá dé, wọ́n dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. [
47. Ẹnìkan sọ fún un pé, “Ìyá rẹ ati àwọn arakunrin rẹ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”]
48. Jesu dá a lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi? Àwọn ta sì ni arakunrin mi?”
49. Ó bá nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Wò ó ìyá mi ati àwọn arakunrin mi nìwọ̀nyí.