19. Kò ní ṣàròyé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní pariwo,bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ ohùn rẹ̀ ní títì.
20. Kò ní dá igi tẹ́ẹ́rẹ́ tí ó tẹ̀ sí meji.Kò ní pa iná tí ó ń jó bẹ́lúbẹ́lú,títí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ yóo fi borí.
21. Ninu orúkọ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu yóo ní ìrètí.”
22. Nígbà náà wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu tí ó ní ẹ̀mí èṣù; ẹ̀mí èṣù yìí ti fọ́ ọ lójú, ó sì mú kí ó yadi. Jesu bá wò ó sàn; ọkunrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì ríran.
23. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń wí pé, “Ó ha lè jẹ́ pé ọmọ Dafidi nìyí bí?”
24. Ṣugbọn nígbà tí àwọn Farisi gbọ́, wọ́n ní, “Ojú lásán kọ́ ni ọkunrin yìí fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde; agbára Beelisebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó ń lò.”
25. Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń rò. Ó bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìlúkílùú tabi ilékílé tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá ń bá ara wọn jà yóo tú.
26. Bí Satani bá ń lé Satani jáde, ara rẹ̀ ni ó ń gbé ogun tì. Báwo ni ìjọba rẹ̀ ṣe lè dúró?
27. Bí ó bá jẹ́ pé agbára Beelisebulu ni èmi fi ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, agbára wo ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà, àwọn ọmọ yín ni yóo ṣe onídàájọ́ yín.