Malaki 4:3-6 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ẹ óo tẹ àwọn eniyan burúkú mọ́lẹ̀, nítorí wọn yóo di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn.

4. “Ẹ ranti òfin ati ìlànà tí mo ti fún Mose, iranṣẹ mi, fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Horebu.

5. “Ẹ wò ó! N óo rán wolii Elija si yín kí ọjọ́ ńlá OLUWA, tí ó bani lẹ́rù náà tó dé.

6. Yóo yí ọkàn àwọn baba pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ wọn, yóo sì yí ti àwọn ọmọ, pada sọ́dọ̀ àwọn baba wọn; kí n má baà fi ilẹ̀ náà gégùn-ún.”

Malaki 4