Malaki 2:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ṣebí ara kan náà ati ẹ̀jẹ̀ kan náà ni Ọlọrun ṣe ìwọ pẹlu rẹ̀? Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, Ọlọrun ń fẹ́ irú ọmọ tí yóo jẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má ṣe hùwà aiṣootọ sí aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín.

16. “Mo kórìíra ìkọ̀sílẹ̀ láàrin tọkọtaya, mo kórìíra irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀ sí olólùfẹ́ ẹni. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe jẹ́ alaiṣootọ sí aya yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”

17. Ọ̀rọ̀ yín ti sú Ọlọrun, sibẹsibẹ ẹ̀ ń bèèrè pé, “Báwo ni a ṣe mú kí ọ̀rọ̀ wa sú u?” Nítorí ẹ̀ ń sọ pé, “Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe burúkú jẹ́ eniyan rere níwájú OLUWA, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn.” Tabi nípa bíbèèrè pé, “Níbo ni Ọlọrun onídàájọ́ òdodo wà?”

Malaki 2